Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yan èdè Yorùbá

 ORIN 145

Ọlọ́run Ṣèlérí Párádísè

Yan Àtẹ́tísí
Ọlọ́run Ṣèlérí Párádísè
WÒÓ
Ọ̀rọ̀
Àwòrán

(Lúùkù 23:43)

 1. 1. Jèhófà ṣe ìlérí fún wa

  Páyé máa di Párádísè.

  Kristi ló máa jẹ́ alákòóso,

  Kò ní síkú àtẹ̀ṣẹ̀ mọ́.

  (ÈGBÈ)

  Ayé yóò di Párádísè.

  Pẹ̀lú ‘gbàgbọ́, ó dájú pé

  Ó máa rí bẹ́ẹ̀. Jésù yóò ṣeé,

  Torí pó máa ńṣe ìfẹ́ Jáà.

 2. 2. Kò ní pẹ́ mọ́ nínú ayé yìí,

  Jésù yóò jí òkú dìde.

  Jésù ti sọ pé: ‘Ìwọ yóò wà

  Pẹ̀lú mi ní Párádísè.’

  (ÈGBÈ)

  Ayé yóò di Párádísè.

  Pẹ̀lú ‘gbàgbọ́, ó dájú pé

  Ó máa rí bẹ́ẹ̀. Jésù yóò ṣeé,

  Torí pó máa ńṣe ìfẹ́ Jáà.

 3. 3. Jésù ṣèlérí Párádísè.

  Ìṣàkóso rẹ̀ ti bẹ̀rẹ̀.

  Ọpẹ́ ni fún Jèhófà Ọba,

  Títí ayé laó máa dúpẹ́.

  (ÈGBÈ)

  Ayé yóò di Párádísè.

  Pẹ̀lú ‘gbàgbọ́, ó dájú pé

  Ó máa rí bẹ́ẹ̀. Jésù yóò ṣeé,

  Torí pó máa ńṣe ìfẹ́ Jáà.