WÒÓ
Ọ̀rọ̀
Àwòrán

(Róòmù 8:20-25)

 1. 1. Àmì tá à ń rí jẹ́ ká mọ̀ pé

  Jèhófà Olódùmarè

  Máa sorúkọ rẹ̀ di mímọ́;

  Àkókò náà kò ní yẹ̀.

  (ÈGBÈ)

  Tẹpá mọ́ṣẹ́, kó o sì wà lójúfò;

  Máa fayọ̀ retí àkókò

  Tá ó wà láàyè títí láé.

 2. 2. Ọmọ Ọlọ́run ti ṣe tán;

  Àkókò tó láti ṣígun

  Bo àwọn ọ̀tá tó ń gbógun,

  Ìṣẹ́gun sì ti dájú.

  (ÈGBÈ)

  Tẹpá mọ́ṣẹ́, kó o sì wà lójúfò;

  Máa fayọ̀ retí àkókò

  Tá ó wà láàyè títí láé.

 3. 3. Ìrora ti pọ̀ jù láyé,

  A mọ̀ pé ìtura dé tán.

  Ọjọ́ Jèhófà sún mọ́lé;

  A máa fìgbàgbọ́ dúró.

  (ÈGBÈ)

  Tẹpá mọ́ṣẹ́, kó o sì wà lójúfò;

  Máa fayọ̀ retí àkókò

  Tá ó wà láàyè títí láé.