Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yan èdè Yorùbá

 ORIN 142

Ká Jẹ́ Kí Ìrètí Wa Lágbára

Yan Àtẹ́tísí
Ká Jẹ́ Kí Ìrètí Wa Lágbára
WÒÓ
Ọ̀rọ̀
Àwòrán

(Hébérù 6:18, 19)

 1. 1. Ọ̀pọ̀ ọdún laráyé ti wà lókùnkùn.

  Gbogbo ìsapá wọn lórí asán ni.

  Aráyé kò lè gbara wọn là rárá;

  Torí ẹlẹ́ṣẹ̀ ni gbogbo wọn.

  (ÈGBÈ)

  Kọrin ayọ̀, Ìjọba náà dé tán!

  Jésù ni Ọba Ìjọba Ọlọ́run.

  Àkóso rẹ̀ yóò mú ìtura wá;

  Fọkàn balẹ̀, má ṣe sọ̀rètí nù láé.

 2. 2. À ń kéde pé ọjọ́ Ọlọ́run sún mọ́lé!

  Gbogbo ìlérí Ọlọ́run ló máa ṣẹ.

  Kò ní síbànújẹ́ mọ́ fún aráyé.

  Kọrin ìyìn s’Olódùmarè.

  (ÈGBÈ)

  Kọrin ayọ̀, Ìjọba náà dé tán!

  Jésù ni Ọba Ìjọba Ọlọ́run.

  Àkóso rẹ̀ yóò mú ìtura wá;

  Fọkàn balẹ̀, má ṣe sọ̀rètí nù láé.