WÒÓ
Ọ̀rọ̀
Àwòrán

(Ìṣípayá 21:1-5)

 1. 1. Wo ara rẹ àtèmi náà

  Bíi pé a wà nínú ayé tuntun.

  Wo bí yóò ṣe rí lára rẹ

  Pé gbogbo ayé wà lálàáfíà.

  Kò sí èèyàn búburú mọ́;

  Ìjọba Ọlọ́run dúró láé.

  Àkókò ìtura ti dé fáráyé

  A ó máa kọrin ìyìn jáde

  látọkàn wá:

  (ÈGBÈ)

  “A dúpẹ́, Jèhófà Ọlọ́run wa.

  Ìjọba Ọmọ rẹ sọ nǹkan dọ̀tun.

  Ayọ̀ kún ọkàn wa, a sì ń kọrin ọpẹ́.

  Kí ògo, ìyìn àtọlá jẹ́ tìrẹ láé.”

 2.  2. Wo ara rẹ, wo èmi náà,

  Bá ó ṣe jọ máa gbádùn láyé tuntun.

  Ìbànújẹ́ kò ní sí mọ́;

  Kò sóhun tó máa dẹ́rù bà wá.

  Ìlérí Ọlọ́run máa ṣẹ:

  Àgọ́ rẹ̀ yóò bo gbogbo ayé.

  Yóò sì jí àwọn tó ń sùn nínú ikú;

  Àwọn àtàwa náà yóò máa

  kọrin ọpẹ́:

  (ÈGBÈ)

  “A dúpẹ́, Jèhófà Ọlọ́run wa.

  Ìjọba Ọmọ rẹ sọ nǹkan dọ̀tun.

  Ayọ̀ kún ọkàn wa, a sì ń kọrin ọpẹ́.

  Kí ògo, ìyìn àtọlá jẹ́ tìrẹ láé.”