Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yan èdè Yorùbá

 ORIN 136

“Ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ Èrè” Látọ̀dọ̀ Jèhófà

Yan Àtẹ́tísí
“Ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ Èrè” Látọ̀dọ̀ Jèhófà
WÒÓ
Ọ̀rọ̀
Àwòrán

(Rúùtù 2:12)

 1. 1. Jèhófà jẹ́ olóòótọ́, ó rí àwọn

  Tó ń fi gbogbo ọkàn wọn sìn ín.

  Ó mọ àwọn ohun tí wọ́n pàdánù

  Bí wọ́n ṣe ń wá Ìjọba rẹ̀.

  Tó o bá ti filé, fẹbí, fọ̀rẹ́ sílẹ̀,

  Gbogbo rẹ̀ ni Ọlọ́run rí.

  Àwọn ará kárí ayé nífẹ̀ẹ́ rẹ;

  Wàá tún ríyè àìnípẹ̀kun.

  (ÈGBÈ)

  Kí Jèhófà fìbùkún síṣẹ́ rẹ,

  Kó fún ọ ní ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ èrè.

  Kó máa ṣọ́ ẹ, kó dáàbò bò ẹ́;

  Jèhófà jólóòótọ́, onínú rere.

 2. 2. Nígbà mí ì, ìdààmú àtìsoríkọ́

  Lè kó ìrẹ̀wẹ̀sì bá wa.

  Àtijẹ àtimu sì lè má rọrùn

  A mọ̀ dájú pé Jèhófà,

  Olùgbọ́ àdúrà tó ṣeé gbára lé,

  Ẹgbẹ́ ará tó nífẹ̀ẹ́ wa,

  Ẹ̀mí Ọlọ́run àtẹ̀kọ́ Ọ̀rọ̀ Rẹ̀,

  Yóò mú ìtùnú wá bá wa.

  (ÈGBÈ)

  Kí Jèhófà fìbùkún síṣẹ́ rẹ,

  Kó fún ọ ní ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ èrè.

  Kó máa ṣọ́ ẹ, kó dáàbò bò ẹ́;

  Jèhófà jólóòótọ́, onínú rere.