WÒÓ
Ọ̀rọ̀
Àwòrán

(Sáàmù 127:3-5)

 1. 1. Tí tọkọtaya bá bímọ,

  Tí àwọn méjèèjì wá di òbí,

  Iṣẹ́ ńlá ni Jèhófà fún wọn

  Pé kí wọ́n tọ́jú ọmọ náà.

  Ẹ̀bùn látọ̀dọ̀ Jèhófà ni.

  Òun ló dá wa, ó sì ní ìfẹ́ wa.

  Ó fáwọn òbí ní ìtọ́ni

  Kí wọ́n lè tọ́ ọmọ wọn dáadáa.

  (ÈGBÈ)

  Jèhófà ló ni ọmọ ‘wọ́ yín,

  Ẹ̀bùn iyebíye ló jẹ́.

  Ẹ̀bùn tó dáa jù tẹ́ ẹ lè fún un ni

  Pé kẹ́ ẹ kọ́ ọ lófin Ọlọ́run.

 2. 2. Ẹ̀yin òbí gbọ́dọ̀ máa fi

  Gbogbo àṣẹ Ọlọ́run sọ́kàn yín.

  Kẹ́ ẹ máa fi kọ́ àwọn ọmọ yín.

  Ohun tẹ́ ẹ gbọ́dọ̀ ṣe nìyẹn.

  Ẹ fi kọ́ wọn tẹ́ ẹ bá ń rìn lọ́nà,

  Tí ẹ bá jí àti kí ẹ tó sùn.

  Wọn yóò máa rántí nígbà gbogbo,

  Wọn yóò sì múnú Jèhófà dùn.

  (ÈGBÈ)

  Jèhófà ló ni ọmọ ‘wọ́ yín,

  Ẹ̀bùn iyebíye ló jẹ́.

  Ẹ̀bùn tó dáa jù tẹ́ ẹ lè fún un ni

  Pé kẹ́ ẹ kọ́ ọ lófin Ọlọ́run.