Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yan èdè Yorùbá

 ORIN 119

Ó Yẹ Ká Ní Ìgbàgbọ́

Yan Àtẹ́tísí
Ó Yẹ Ká Ní Ìgbàgbọ́
WÒÓ
Ọ̀rọ̀
Àwòrán

(Hébérù 10:38, 39)

 1. 1. Ọlọ́run bá àwọn èèyàn sọ̀rọ̀

  Nípasẹ̀ àwọn wòlíì rẹ̀.

  Lónìí, ó ń lo Ọmọ rẹ̀ láti sọ

  Pé ká ronú pìwà dà.

  (ÈGBÈ)

  Ṣé a nígbàgbọ́ tó jinlẹ̀?

  Ohun tá à ń ṣe gbọ́dọ̀ fi hàn.

  Ìgbàgbọ́ yìí ṣe pàtàkì;

  Ìgbàgbọ́ wa yóò mú kí á níyè.

 2. 2. À ń fi ayọ̀ tẹ̀ lé àṣẹ Jésù

  Pé ká wàásù ìhìn rere.

  À ń fi ìgboyà sọ̀rọ̀ ìrètí

  Tí Ọlọ́run ṣèlérí.

  ÈGBÈ)

  Ṣé a nígbàgbọ́ tó jinlẹ̀?

  Ohun tá à ń ṣe gbọ́dọ̀ fi hàn.

  Ìgbàgbọ́ yìí ṣe pàtàkì;

  Ìgbàgbọ́ wa yóò mú kí á níyè.

 3. 3. Ìdákọ̀ró ni ìgbàgbọ́ wa jẹ́,

  Yóò jẹ́ ká lè nífaradà.

  Tá a bá gbẹ́kẹ̀ lé Jáà, a ò ní bẹ̀rù;

  Torí ìgbàlà dé tán.

  ÈGBÈ)

  Ṣé a nígbàgbọ́ tó jinlẹ̀?

  Ohun tá à ń ṣe gbọ́dọ̀ fi hàn.

  Ìgbàgbọ́ yìí ṣe pàtàkì;

  Ìgbàgbọ́ wa yóò mú kí á níyè.