WÒÓ
Ọ̀rọ̀
Àwòrán

(2 Pétérù 3:15)

 1. 1. Jèhófà, alágbára gíga;

  Ìwọ fẹ́ràn ohun tó tọ́.

  Ìwà búburú pọ̀ láyé,

  Ó sì ń mú ká máa kérora.

  A mọ̀ pé o ṣì máa fòpin sí i

  Lákòókò tó tọ́ ní ojú rẹ.

  (ÈGBÈ)

  Ìrètí wa ń lágbára sí i,

  A dúpẹ́, a yin orúkọ rẹ.

 2. 2. Ẹgbẹ̀rún ọdún lójú èèyàn

  Dà bí ọjọ́ kan lójú rẹ.

  Ọjọ́ ńlá rẹ yóò dé láìpẹ́;

  Kì yóò falẹ̀, béèyàn ṣe ń rò.

  Gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ ni o kórìíra,

  O fẹ́ kí ẹlẹ́ṣẹ̀ yí pa dà.

  (ÈGBÈ)

  Ìrètí wa ń lágbára sí i,

  A dúpẹ́, a yin orúkọ rẹ.