WÒÓ
Ọ̀rọ̀
Àwòrán

(Jòhánù 14:27)

 1. 1. Yin Ọlọ́run àlàáfíà,

  Ọlọ́run ìfẹ́.

  Ó máa fòpin sí ogun,

  Yóò mú ‘rẹ́pọ̀ wá.

  Ọmọ rẹ̀, Jésù Kristi

  Ọba Àlàáfíà,

  Yóò ja ìjà òdodo;

  Yóò málàáfíà wá.

 2. 2. A kì í sọ̀rọ̀ búburú

  Tó lè fa ìjà.

  A ti dẹni àlàáfíà

  Pẹ̀l’áwọn èèyàn.

  Ó yẹ ká máa dárí ji

  Àwọn tó ṣẹ̀ wá.

  Yóò jẹ́ ká wà lálàáfíà

  Bíi Jésù Kristi.

 3. 3. Àlàáfíà Ọlọ́run wa

  Máa ń mú ‘bùkún wá.

  Àwọn òfin rẹ̀ dára;

  A ó máa ṣègbọràn.

  Bó bá ti lè ṣeé ṣe tó,

  Ká wà lálàáfíà.

  Láìpẹ́, àlàáfíà máa wà

  Ní gbogbo ayé.