Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

“Fi Ayọ̀ Kọrin” sí Jèhófà

 ORIN 106

Bá A Ṣe Lè Ní Ìfẹ́

Yan Àtẹ́tísí
Bá A Ṣe Lè Ní Ìfẹ́
WÒÓ
Ọ̀rọ̀

(1 Kọ́ríńtì 13:1-8)

 1. 1. À ń gbàdúrà s’Ọ́lọ́run wa pé

  Ká lè f’ànímọ́ rẹ̀ ṣèwà hù.

  Ìfẹ́ ló gbawájú nínú wọn;

  Ẹ̀mí mímọ́ máa jẹ́ ká nífẹ̀ẹ́.

  Bá a tiẹ̀ lẹ́bùn, tá a sì nígboyà,

  Tá a nímọ̀, àmọ́ tá a kò nífẹ̀ẹ́,

  Asán ni gbogbo ẹ̀bùn náà jẹ́.

  Torí náà, kífẹ̀ẹ́ máa darí wa.

 2. 2. Ìfẹ́ máa ń fúnni látọkàn wá.

  Ìfẹ́ kì í mọ tara rẹ̀ nìkan.

  Kì í fàyè gba èrò tí kò dáa;

  Ó ń mú ká máa dárí jira wa.

  Ìfẹ́ ń fara da ohun gbogbo;

  Ó ń jẹ́ ká lè gbẹ́rù tó wúwo.

  Ká fìfẹ́ hàn ní gbogbo ọ̀nà;

  Ìfẹ́ tòótọ́ kò ní yẹ̀ láéláé.