Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yan èdè Yorùbá

 ORIN 104

Ẹ̀bùn Ọlọ́run Ni Ẹ̀mí Mímọ́

Yan Àtẹ́tísí
Ẹ̀bùn Ọlọ́run Ni Ẹ̀mí Mímọ́
WÒÓ
Ọ̀rọ̀
Àwòrán

(Lúùkù 11:13)

 1. 1. Bàbá aláàánú ni ọ́, Jèhófà.

  O nífẹ̀ẹ́ wa bá a tiẹ̀ jẹ́lẹ́ṣẹ̀.

  Jọ̀ọ́ ràn wá lọ́wọ́, jẹ́ kára tù wá.

  Fi ẹ̀mí mímọ́ rẹ tù wá nínú.

 2. 2. Ẹ̀ṣẹ̀ tá a jogún ń mú ká ṣàṣìṣe,

  Ká sì pàdánù ojúure rẹ.

  Bàbá, a bẹ̀ ọ́, gbọ́ àdúrà wa:

  Jọ̀ọ́, jẹ́ kí ẹ̀mí rẹ máa darí wa.

 3. 3. Tá a bá sorí kọ́ tàbí tó rẹ̀ wá,

  Bàbá, jẹ́ kí ẹ̀mí mímọ́ rẹ

  Fún wa lágbára bíi t’ẹyẹ idì;

  Jẹ́ ká máa rí ẹ̀mí mímọ́ rẹ gbà.