WÒÓ
Ọ̀rọ̀
Àwòrán

(Ìṣípayá 4:11)

 1. 1. Alágbára Ńlá ni Ọ́, Jèhófà.

  Ìwọ l’Orísun ìmọ́lẹ̀ àtìyè.

  Ohun tó o dá ń fi agbára rẹ hàn;

  Ayé àtọ̀run náà ń jẹ́rìí sí i.

 2. 2. Ìṣàkóso rẹ jẹ́ ti òdodo,

  Àwọn àṣẹ rẹ lo sì ti sọ fún wa.

  Bí a ṣe ń ka Bíbélì, à ń rí i pé

  Ọgbọ́n rẹ ti wá túbọ̀ ń yé wa.

 3. 3. Ìfẹ́ ni ànímọ́ rẹ tó ga jù.

  Àwọn oore rẹ kọjá àfẹnusọ.

  A ó fìtara kéde orúkọ rẹ,

  Àtàwọn ànímọ́ rẹ tó pọ̀.