Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yan èdè Yorùbá

Oníṣẹ́ Àrà, Mo Gbé Ọ Ga!

Oníṣẹ́ Àrà, Mo Gbé Ọ Ga!
WÒÓ
Ọ̀rọ̀
Àwòrán

Wà á jáde:

 1. 1. B’ọ́yẹ̀ ṣe ń là, ẹyẹ ńkọ orin tó dùn.

  B’óòrùn ṣe ń yọ, ìràwọ̀ pa rẹ́ lójú ọ̀run.

  Oòrùn òwúrọ̀ ń tàn sára igi,

  Afẹ́fẹ́ ìgbà ẹ̀ẹ̀rùn sì tùn wá ńfẹ́ yẹ́ẹ́.

  (ṢÁÁJÚ-ÈGBÈ)

  Màá f’orin yìn ọ́, “Jáà, Ọlọ́run mi,

  Ìyanu ni gbogbo iṣẹ́ rẹ.” Iṣẹ́ rẹ tóbi,

  Kí lèèyàn jẹ́, tó o fi ńrántí wa?

  (ÈGBÈ)

  Oníṣẹ́ àrà, mo wá gbé ọ ga.

  Oníṣẹ́ àrà, mo wá gbé ọ ga.

  Mo gbé ọ ga.

 2. 2. Àwọn ẹranko lóríṣiríṣi​—

  Iṣẹ́ àrà Jèhófà ni gbogbo wọn ńgbé yọ.

  Látorí òkè dé ìsàlẹ̀ òkun,

  Kí gbogbo alààyè máa fìyìn fún ọ.

  (ṢÁÁJÚ-ÈGBÈ)

  Màá f’orin yìn ọ́, “Jáà, Ọlọ́run mi,

  Ìyanu ni gbogbo iṣẹ́ rẹ.” Iṣẹ́ rẹ tóbi,

  Kí lèèyàn jẹ́, tó o fi ńrántí wa?

  (ÈGBÈ)

  Oníṣẹ́ àrà, mo wá gbé ọ ga.

  Oníṣẹ́ àrà, mo wá gbé ọ ga.

  Mo gbé ọ ga.

  (ÀSOPỌ̀)

  Tá a bá ńronú kọjá ohun tá à ńrí,

  A máa túbọ̀ mọ sí i nípa Jèhófà Ẹlẹ́dàá wa.

  (ṢÁÁJÚ-ÈGBÈ)

  Màá f’orin yìn ọ́, “Jáà, Ọlọ́run mi,

  Ìyanu ni gbogbo iṣẹ́ rẹ.” Iṣẹ́ rẹ tóbi,

  Kí lèèyàn jẹ́, tó o fi ńrántí wa?

  (ÈGBÈ)

  Oníṣẹ́ àrà, mo wá gbé ọ ga.

  Oníṣẹ́ àrà, mo wá gbé ọ ga.

  Oníṣẹ́ àrà, mo wá gbé ọ ga.

  Oníṣẹ́ àrà, mo wá gbé ọ ga.

  Oníṣẹ́ àrà, mo wá gbé ọ ga.

  Mo gbé ọ ga.