WÒÓ
Ọ̀rọ̀
Àwòrán

Wà á jáde:

 1. 1.Ò ń gbọ́ tẹ́yẹ ń kọrin tó dùn,

  Tójú ọjọ́ sì rẹwà.

  Bó o sì ṣe ń lọ lójú ọ̀nà,

  O wá rí i bóòrùn tó yọ ṣe ń tàn.

  Ò ń káwọn òkú káàbọ̀,

  Ó sì ń yà ọ́ lẹ́nu gan-an

  Pó o wà ní Párádísè;

  Ó sì ti fẹ́rẹ̀ẹ́ dé tán.

 2. 2.Ilé kan wà ní ìsàlẹ̀

  Ìkan wà lórí òkè.

  Àwọn kan ń kọrin létídò

  Bí omi tó mọ́ lóló ṣe ń ṣàn.

  Àkókò ìkórè tó.

  Ẹ jẹ́ kí ‘kórè bẹ̀rẹ̀.

  A ti wà láyé tuntun;

  Ó sì ti fẹ́rẹ̀ẹ́ dé tán.

  (ÀSOPỌ̀)

  Ó yẹ ká sọ fáwọn èèyàn

  Nípa ìrètí tá a ní yìí

  Kò sẹ́kún mọ́, kò síkú mọ́.

  Ará dọ̀tun, ayé tuntun.

 3. 3.Inú gbogbo èèyàn ló ń dùn.

  Ò ń gbọ́ òórùn tó tura.

  O wá ń kí àwọn èèyàn rẹ.

  Kò sẹ́ṣẹ̀, èèyàn ti di pípé.

  A dúpẹ́ lọ́wọ́ Jèhófà

  Torí ‘fẹ tó ní sí wa.

  Ìbùkún ńlá ló sì jẹ́

  Ó sì ti fẹ́rẹ̀ẹ́ dé tán.

  (ÀSOPỌ̀)

  Lójoojúmọ́, mò ń sọ pé:

  “Inú mi dùn pé mo rí ọ!”

  Ṣe ló dà bí àlá sí mi,

  Pé mo lè tún pa dà rí ọ.

 4. 4.Mo ti ń fojú sọ́nà

  Láti rí ayé tuntun.

  Jèhófà ló ṣèlérí yìí.

  Ọ̀rọ̀ rẹ̀ kò ní lọ láìṣẹ.

  Tí n bá rántí ayé tuntun,

  Ó máa ń fọkàn mi balẹ̀.

  Mo ti ń retí ọjọ́ náà,

  Ó sì ti fẹ́rẹ̀ẹ́ dé tán.