Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Àwọn Orin Wa Míì

Mo Ṣì Lè Dìde

Mo Ṣì Lè Dìde
WÒÓ
Ọ̀rọ̀
Àwòrán

Wà á jáde:

 1. 1. Ìsoríkọ́, ìbànújẹ́, ni mò ń bá yí.

  Jèhófà, mo gbà pé mo ṣàṣìṣe.

  Gbogbo nǹkan ti sú mi, jọ̀wọ́ wá ràn mí lọ́wọ́.

  Mo ṣe tán láti pa dà sọ́dọ̀ rẹ.

  (ÈGBÈ)

  Mo rántí ohun tó o kọ́ mi, káyé mi lè dáa;

  Bó o ṣe ń fi Bíbélì rán mi létí

  Pé tí n bá tiẹ̀ ṣàṣìṣe, tí n bá tiẹ̀ ṣubú,

  Mo ṣì lè dìde.

 2. 2.Mo mọ àwọn tó nífẹ̀ẹ́ mi,

  Tọ́rọ̀ mi jẹ lógún,

  Tó nífẹ̀ẹ́ Jèhófà látọkàn.

  Ṣe lọ̀rọ̀ rẹ dà bí ìmọ́lẹ̀ tó ń tọ́ mi sọ́nà,

  Kí n má bàa kúrò ní ọ̀nà ìyè.

  (ÀSOPỌ̀)

  Ohun tí mò ń rí, máa ń rán mi létí òtítọ́ tí mo mọ̀:

  Pé òpin máa tó dé.

  (ÈGBÈ)

  Jọ̀ọ́, Jèhófà Bàbá mi, gbọ́ àdúrà mi.

  Ojú rẹ ni mò ń wò, ràn mí lọ́wọ́.

  O sọ pé nígbàkigbà tí n bá kọsẹ̀,

  Mo ṣì lè dìde.

  (ÌSOPỌ̀)

  Ọ̀rọ̀ mi yé ọ, Jèhófà; mo nílò ìrànlọ́wọ́ rẹ.

  O mọ bó ṣe ń ṣe mí, bí kò bá tiẹ̀ yé àwọn míì.

  Ìwọ nìkan lo rọ́kàn mi.

  (ÈGBÈ)

  Lálẹ́ yìí, mo pinnu pé màá lọ sí Gbọ̀ngàn Ìjọba,

  Lọ́dọ̀ àwọn tó nífẹ̀ẹ́ mi.

  Tí mo bá tiẹ̀ ṣàṣìṣe, tí n bá tiẹ̀ ṣubú, mo ṣì lè dìde.

  Mo ṣì lè dìde.