Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Àwọn Orin Wa Míì

Ìyanu Ni Iṣẹ́ Rẹ

Ìyanu Ni Iṣẹ́ Rẹ
WÒÓ
Ọ̀rọ̀
Àwòrán

Wà á jáde:

 1. 1. Ọ̀pọ̀ ìbùkún ni Ìjọba rẹ ti mú wá.

  Ó ti jẹ́ kí n ní Bíbélì, kí n sì mọ òtítọ́.

  O tún yan ẹrú olóòótọ́, ó ń fọ̀rọ̀ rẹ yé wa.

  O fàwọn alàgbà kẹ́ mi, wọ́n ń fìfẹ́ tọ́jú mi.

  Àwọn àpéjọ wa máa ń ládùn, ó máa ń lóyin.

  Ọdọọdún ni mo máa ń sọ pé, “Tọdún yìí ló dùn jù!”

  Ohun tí à ń kọ́ nípàdé fi hàn pó o nífẹ̀ẹ́ wa,

  Ó ń kọ́ mi bí màá ṣe wàásù, kí n sì máa ṣèfẹ́ rẹ.

  (ÈGBÈ)

  Ìyanu niṣẹ́ rẹ,

  A sì mọyì Ìjọba rẹ.

  Ọ̀pọ̀ nǹkan ló ti ṣe.

  Ọlọ́run tó dára ni ọ, ọkàn wa balẹ̀ gan-an.

  À ń retí ìbùkún tí Ìjọba rẹ yóò mú wá.

 2. 2. Ọlá ńlá lo dá wa pé ká máa bá ọ ṣiṣẹ́,

  À ń fìtara wàásù ká lè fi hàn pá a nífẹ̀ẹ́ rẹ.

  Ò ń fi Ọ̀rọ̀ rẹ yé wa, ò ń fi wá lọ́kàn balẹ̀,

  Ọ̀rọ̀ rẹ ń jẹ́ káyé wa dáa; ó ń fòtítọ́ hàn wá.

  Tí mo bá ń gbọ́ orin wa, ó máa ń wọ̀ mí lọ́kàn.

  Ìjọsìn Ìdílé wa ń ran ìdílé wa lọ́wọ́.

  Ibi yòówù ká wà, èdè yòówù kí a máa sọ,

  Ọmọ ìyá ni gbogbo wa, irú èyí ṣọ̀wọ́n!

  (ÈGBÈ)

  Ìyanu niṣẹ́ rẹ,

  A sì mọyì Ìjọba rẹ.

  Ọ̀pọ̀ nǹkan ló ti ṣe.

  Ọlọ́run tó dára ni ọ, ọkàn wa balẹ̀ gan-an.

  À ń retí ìbùkún tí Ìjọba rẹ yóò mú wá.