WÒÓ
Ọ̀rọ̀
Àwòrán

Wà á jáde:

 1. 1. Lát’ọmọdé làwọn òbí ti ń kọ́ mi.

  Òye ń yé wa bá a ṣe kéré tó lákòókò yẹn.

  Bàámi máa ń ka Bíbélì fún mi lálẹ́,

  Ó wá mọ́ mi lára láti máa ka Bíbélì.

  Tí n bá dá wà, màá gbé Bíbélì, màá bẹ̀rẹ̀ sí í kà á.

  Mo rántí ohun t’Ìwé Mímọ́ sọ pó lè sọ mí d’alágbára.

  (ÈGBÈ)

  Ìkẹ́kọ̀ọ́ dára;

  Ṣe ló dà bí igi tá a gbìn sétídò.

  Ìkẹ́kọ̀ọ́ dára;

  Wàá d’alágbára, wàá tún ṣàṣeyọrí.

  Ìkẹ́kọ̀ọ́ dára;

  Wàá fìdí múlẹ̀ bí ‘gi tó ta gbòǹgbò.

  Ìkẹ́kọ̀ọ́ dára;

  Wàá d’alágbára, ẹ̀rù kan kò ní bà ọ́.

 2. 2. Kí ni màá ṣe báǹfààní ‘jẹ́rìí yọjú,

  Tí tèmi yàtọ̀ láàárín àwọn ‘mọléèwé mi??

  Ohun tó yẹ kí n ṣe ti wà ní sẹpẹ́.

  Ọkàn mi balẹ̀, wọ́n ti kọ́ mi ní kékeré.

  Tí n bá dá wà, màá gbé Bíbélì, màá bẹ̀rẹ̀ sí í kà á.

  Mo rántí ohun t’Ìwé Mímọ́ sọ pó lè sọ mí d’alágbára.

  (ÈGBÈ)

  Ìkẹ́kọ̀ọ́ dára;

  Ṣe ló dà bí igi tá a gbìn sétídò.

  Ìkẹ́kọ̀ọ́ dára;

  Wàá d’alágbára, wàá tún ṣàṣeyọrí.

  Ìkẹ́kọ̀ọ́ dára;

  Wàá fìdí múlẹ̀ bí ‘gi tó ta gbòǹgbò.

  Ìkẹ́kọ̀ọ́ dára;

  Wàá d’alágbára, ẹ̀rù kan kò ní bà ọ́.

  (ÀSOPỌ̀)

  Ohun tó ràn mí lọ́wọ́,

  Ó lè jóhun yẹn gangan

  Ló máa ran ẹlòmíì lọ́wọ́, táá sì bọ́ sákòókò gan-an.

  (ÈGBÈ)

  Ìkẹ́kọ̀ọ́ dára.

  Ìkẹ́kọ̀ọ́ dára.

  Ìkẹ́kọ̀ọ́ dára.

  Ìkẹ́kọ̀ọ́ dára.

  Ìkẹ́kọ̀ọ́ dára;

  Ṣe ló dà bí igi tá a gbìn sétídò.

  Ìkẹ́kọ̀ọ́ dára;

  Wàá d’alágbára, wàá tún ṣàṣeyọrí.

  Ìkẹ́kọ̀ọ́ dára;

  Wàá fìdí múlẹ̀ bí ‘gi tó ta gbòǹgbò.

  Ìkẹ́kọ̀ọ́ dára;

  Wàá d’alágbára, ẹ̀rù kan kò ní bà ọ́.