Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yan èdè Yorùbá

Àwọn Ìránnilétí Rẹ Ràn Mí Lọ́wọ́

Àwọn Ìránnilétí Rẹ Ràn Mí Lọ́wọ́
WÒÓ
Ọ̀rọ̀
Àwòrán

Wà á jáde:

 1. 1. Kí ni kí n ṣe? Tá ni kí n fi lọ̀?

  Àpèjẹ lásán ni, kò sóhun tá á ṣẹlẹ̀.

  Tí mo bá sì lọ síbẹ̀, kò lè ṣíṣòro.

  Àmọ́ tíṣòro bá lọ dé? Kí ni màá wá ṣe?

  Kí ni kí n ṣe? Ti ta ni kí n ṣe?

  Tí nǹkan bá lọ yíwọ́, tí wàhálà bá dé?

  Tádánwò bá dé, tó dán ìgbàgbọ́ mi wò.

  Kí ni màá wá ṣe sọ́rọ̀ yìí? Jéhofà, gbọ́ àdúrà mi.

  (ÈGBÈ)

  Mo pa àṣẹ rẹ mọ́, mo fẹ́ràn wọn gan-an.

  Màá fi sọ́kàn ní gbogbo ọjọ́ ayé mi.

  Ọ̀rọ̀ rẹ sì ti ràn mí lọ́wọ́ láti lóye ohun tó tọ́.

 2. 2. Màá wonú Ọ̀rọ̀ rẹ, kí n lè ṣohun tó tọ́.

  Kí n má ba lọ́wọ́ sí ohun tó jẹ́ ẹ̀ṣẹ̀,

  Torí ó dájú pé ẹlẹ́ṣẹ̀ á jìyà.

  Ohun tó dára jù fún mi​—⁠ni kí n ṣe ìfẹ́ Jáà.

  (ÈGBÈ)

  Mo pa àṣẹ rẹ mọ́, mo fẹ́ràn wọn gan-an.

  Wọ́n fún mi lókun, wọ́n sì jẹ́ n ṣohun tó tọ́.

  Ọ̀rọ̀ rẹ sì ti ràn mí lọ́wọ́ láti lóye ohun tó tọ́.

  (ÈGBÈ)

  Mo pa àṣẹ rẹ mọ́, mo fẹ́ràn wọn gan-an.

  Wọ́n fún mi lókun, wọ́n sì jẹ́ n ṣohun tó tọ́.

  Bí mo ṣe ń ka ọ̀rọ̀ rẹ layé mi ń dára.

  Torí mo ní Ọ lẹ́gbẹ̀ẹ́ mi ọkàn mi balẹ̀.

  Ọ̀rọ̀ rẹ ti ràn mí lọ́wọ́ láti lóye ohun tó tọ́.