Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Àwọn Orin Wa Míì

A Nílò Ìgbàgbọ́

A Nílò Ìgbàgbọ́

Wà á jáde:

 1. 1. Ìrònú gbọkàn mi, ó máyé sú mi.

  Mo gbádùn ọ̀rọ̀ yín, mo fẹ́ gbọ́ sí i;

  Ọ̀rọ̀ tẹ́ ẹ sọ, mo fẹ́ gbọ́ sí i.

  Ọ̀pọ̀ ìbéèrè mi lẹ dáhùn lọ́jọ́ yẹn.

  Ìrònú tó gbọkàn mi tẹ́lẹ̀ pòórá;

  Gbogbo ‘dààmú mi ti fò lọ.

  (ÈGBÈ)

  Bá a tiẹ̀ lọ́pọ̀ ìdíwọ́,

  A nílò ìgbàgbọ́.

  Báwọn ‘ṣòro wa tilẹ̀ pọ̀,

  A nílò ìgbàgbọ́;

  Ká nígbàgbọ́.

 2. 2. Mo fẹ́ láti wàásù ohun tí mo kọ́.

  Mo ṣe tán, iṣẹ́ yá. Ó yá, ká lọ.

  Mo ti ṣe tán

  Láti lọ wàásù.

  Ìgbàgbọ́ mi dà bí iná tó ń jó lọ́kàn.

  Mo gbọ́dọ̀ jẹ́ kó máa jó, kó má ṣe kú;

  Kó lè máa jó ní ọkàn mi.

  (ÈGBÈ)

  Bá a tiẹ̀ lọ́pọ̀ ìdíwọ́,

  Àmọ́ mo rántí pé:

  Báwọn ‘ṣòro wa tilẹ̀ pọ̀,

  A nílò ìgbàgbọ́;

  Ká nígbàgbọ́.

  (ÀSOPỌ̀)

  Ó máa ń súni tá a bá kojú ìṣòro.

  Ṣáà máa gbàdúrà sí Jáà kó o lè túbọ̀ sún mọ́ Jèhófà.

  Ó ní, “Tó o bá lè gbẹ́kẹ̀ lé mi,

  Màá fún ẹ lókun, wàá sì rí i

  Pé tíṣòro bá dé,

  Màá dúró tì ẹ́.”

  (ÈGBÈ)

  Bá a tiẹ̀ lọ́pọ̀ ìdíwọ́,

  Àmọ́ mo rántí pé:

  Báwọn ‘ṣòro wa tilẹ̀ pọ̀,

  A nílò ìgbàgbọ́.

  (ÈGBÈ)

  Ó ti wá dá mi lójú,

  A nílò ìgbàgbọ́.

  Báwọn ‘ṣòro wa tilẹ̀ pọ̀,

  A nílò ìgbàgbọ́;

  Ká nígbàgbọ́.