Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

"Fi Ayọ̀ Kọrin" sí Jèhófà

 ORIN 37

Máa Sin Jèhófà Tọkàntọkàn

Yan Àtẹ́tísí
Máa Sin Jèhófà Tọkàntọkàn

(Mátíù 22:37)

 1. 1. Jèhófà Ọba Aláṣẹ,

  Ìwọ ni mo fẹ́ máa gbọ́ràn sí.

  Mo nífẹ̀ẹ́ rẹ tọkàntọkàn.

  Ìwọ ni màá fi ayé mi sìn.

  Mo fẹ́ràn ìránnilétí rẹ,

  Mo sì ń pàwọn àṣẹ rẹ mọ́.

  (ÈGBÈ)

  Jèhófà, mo nífẹ̀ẹ́ rẹ gan-an.

  Màá fi gbogbo ọkàn mi sìn ọ́.

 2. 2. Gbogbo iṣẹ́ rẹ ń gbé ọ ga;

  Láyé lọ́run, wọ́n ń fògo rẹ hàn.

  Èmi náà fẹ́ máa fokun mi

  Kéde orúkọ rẹ fáráyé.

  Màá fi gbogbo ayé mi sìn ọ́,

  Màá sì jẹ́ olóòótọ́ sí ọ.

  (ÈGBÈ)

  Jèhófà, mo nífẹ̀ẹ́ rẹ gan-an.

  Màá fi gbogbo ọkàn mi sìn ọ́.