Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

"Fi Ayọ̀ Kọrin" sí Jèhófà—Èyí tí Kò Lámì Orin

 ORIN 97

Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run Ló Ń Mú Ká Wà Láàyè

Yan Àtẹ́tísí
Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run Ló Ń Mú Ká Wà Láàyè

(Mátíù 4:4)

 1. 1. A nílò Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run

  Ká lè máa wà láàyè.

  Oúnjẹ tara nìkan kò tó

  Láti gbẹ́mìí wa ró.

  Tá a bá ńgbọ́ Ọ̀rọ̀ Jèhófà,

  Ayé wa yóò dára.

  (ÈGBÈ)

  Oúnjẹ tara nìkan kò tó

  Láti gbẹ́mìí wa ró.

  Ọ̀r’Ọlọ́run ṣe pàtàkì

  Ká lè máa wà láàyè.

 2. 2. Ọ̀rọ̀ inú Ìwé Mímọ́

  Kọ́ wa lọ́pọ̀ ẹ̀kọ́.

  Ó sọ̀rọ̀ àwọn olóòótọ́

  Tí wọ́n ní ìgbàgbọ́.

  Àpẹẹrẹ wọn ńfún wa lókun;

  Ó ńgbé ‘gbàgbọ́ wa ró.

  (ÈGBÈ)

  Oúnjẹ tara nìkan kò tó

  Láti gbẹ́mìí wa ró.

  Ọ̀r’Ọlọ́run ṣe pàtàkì

  Ká lè máa wà láàyè.

 3.  3. Táa bá ńka Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run,

  Yóò máa tù wá nínú.

  Tí a bá kojú ìṣòro,

  Ó máa ràn wá lọ́wọ́.

  Ká jẹ́ kí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run

  Máa wà ní ọkàn wa.

  (ÈGBÈ)

  Oúnjẹ tara nìkan kò tó

  Láti gbẹ́mìí wa ró.

  Ọ̀r’Ọlọ́run ṣe pàtàkì

  Ká lè máa wà láàyè.