Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

"Fi Ayọ̀ Kọrin" sí Jèhófà—Èyí tí Kò Lámì Orin

 ORIN 93

Bù Kún Ìpàdé Wa

Yan Àtẹ́tísí
Bù Kún Ìpàdé Wa

(Hébérù 10:24, 25)

 1. 1. Ìbùkún rẹ ṣe pàtàkì

  Bá a ṣe ń pé jọ fún ‘jọsìn.

  A bẹ̀bẹ̀ pé kó o bù kún wa,

  Kẹ́mìí rẹ wà pẹ̀lú wa.

 2. 2. Jọ̀ọ́, Jèhófà, fi Ọ̀rọ̀ rẹ

  Kọ́ wa, kó wọ̀ wá lọ́kàn.

  Kọ́ ahọ́n wa ká lè jẹ́rìí,

  Ká lè jọ́sìn rẹ dáadáa.

 3. 3. Jèhófà, bù kún ‘pàdé wa,

  Jọ̀ọ́, jẹ́ ká wà níṣọ̀kan.

  Kí ọ̀rọ̀ àti ìṣe wa

  Máa gbé orúkọ rẹ ga.