Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

"Fi Ayọ̀ Kọrin" sí Jèhófà—Èyí tí Kò Lámì Orin

 ORIN 89

Gbọ́, Ṣègbọràn, Kó O sì Gba Ìbùkún

Yan Àtẹ́tísí
Gbọ́, Ṣègbọràn, Kó O sì Gba Ìbùkún
WÒÓ
Ọ̀rọ̀

(Lúùkù 11:28)

 1. 1. Aláyọ̀ làwọn tó ń gbọ́rọ̀ Ọlọ́run,

  Tí wọ́n ń fetí sẹ́kọ̀ọ́ Jésù Kristi;

  Ìbàlẹ̀ ọkàn, ìdùnnú, àlàáfíà,

  Yóò jẹ́ tàwọn tó bá jónígbọràn.

  (ÈGBÈ)

  Gbọ́, ṣègbọràn, gbàbùkún,

  Tí Ọlọ́run bá ń sọ̀rọ̀.

  Tó o bá fẹ́ máa múnú Jèhófà dùn,

  Ìgbọràn ṣe pàtàkì.

 2. 2. Tá a bá jẹ́ onígbọràn sí Ọlọ́run,

  Ìgbésí ayé wa yóò dára gan-an.

  Ó máa dà bí ilé orí àpáta

  Tó lágbára, tó sì fìdí múlẹ̀.

  (ÈGBÈ)

  Gbọ́, ṣègbọràn, gbàbùkún,

  Tí Ọlọ́run bá ń sọ̀rọ̀.

  Tó o bá fẹ́ máa múnú Jèhófà dùn,

  Ìgbọràn ṣe pàtàkì.

 3. 3. Tí a bá fetí sí ohùn Jèhófà,

  Tá à ń tẹ̀ lé àṣẹ àti ‘lànà rẹ̀,

  A máa dà bí igi tá a gbìn sétídò,

  Tó ń so èso rẹ̀ lákòókò tó yẹ.

  (ÈGBÈ)

  Gbọ́, ṣègbọràn, gbàbùkún,

  Tí Ọlọ́run bá ń sọ̀rọ̀.

  Tó o bá fẹ́ máa múnú Jèhófà dùn,

  Ìgbọràn ṣe pàtàkì.