Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

"Fi Ayọ̀ Kọrin" sí Jèhófà—Èyí tí Kò Lámì Orin

 ORIN 88

Mú Mi Mọ Àwọn Ọ̀nà Rẹ

Yan Àtẹ́tísí
Mú Mi Mọ Àwọn Ọ̀nà Rẹ
WÒÓ
Ọ̀rọ̀

(Sáàmù 25:4)

 1. 1. Bàbá wa ọ̀run, a ti pé jọ báyìí,

  Kó o lè kọ́ wa, ká sì jọ́sìn rẹ.

  Ṣe ni Ọ̀rọ̀ rẹ dà bí ìmọ́lẹ̀ tí

  Ó ń tọ́ wa sọ́nà ká lè ríyè.

  (ÈGBÈ)

  Jọ̀ọ́, Jèhófà, kọ́ mi ní ọ̀nà rẹ,

  Jẹ́ kí n lè máa fetí sí àṣẹ rẹ.

  Mú mi mọ àwọn ọ̀nà òdodo,

  Kí òfin rẹ sì máa múnú mi dùn.

 2. 2. Àwọn ọ̀nà ọgbọ́n rẹ kò láfiwé;

  Ìdájọ́ òdodo lo máa ń ṣe.

  Àwọn ẹ̀kọ́ rẹ ń tọ́ wa sọ́nà òótọ́,

  Ọ̀rọ̀ tó o sọ máa wà títí láé.

  (ÈGBÈ)

  Jọ̀ọ́, Jèhófà, kọ́ mi ní ọ̀nà rẹ,

  Jẹ́ kí n lè máa fetí sí àṣẹ rẹ.

  Mú mi mọ àwọn ọ̀nà òdodo,

  Kí òfin rẹ sì máa múnú mi dùn.