Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

"Fi Ayọ̀ Kọrin" sí Jèhófà—Èyí tí Kò Lámì Orin

 ORIN 82

Ẹ Jẹ́ “Kí Ìmọ́lẹ̀ Yín Máa Tàn”

Yan Àtẹ́tísí
Ẹ Jẹ́ “Kí Ìmọ́lẹ̀ Yín Máa Tàn”

(Mátíù 5:16)

 1. 1. Àṣẹ Jésù ni pé

  Kí ‘mọ́lẹ̀ wa tàn.

  Kí ìmọ́lẹ̀ wa hàn

  Gbangba sáráyé.

  Ìwé Mímọ́ ńkọ́ wa

  Ní ìwà rere

  Tá a gbọ́dọ̀ máa mú dàgbà

  Nínú ayé wa.

 2. 2. Bá a ṣe ń wàásù fáwọn

  Èèyàn tá à ń pàdé,

  Ẹ̀kọ́ ọ̀r’Ọlọ́run

  Máa ràn wọ́n lọ́wọ́.

  Kí wọ́n lè ṣàtúnṣe

  Nínú ayé wọn;

  Kí wọ́n lè yàn fúnra wọn

  Láti wá sin Jáà.

 3. 3. Ìwà rere tá à ń hù

  Ń tàn bí ìmọ́lẹ̀.

  Ọ̀rọ̀ ẹnu wa náà

  Sì tún ń gbéni ró.

  Bí a tiẹ̀ ń gbé nínú

  Ayé Sátánì,

  Ìmọ́lẹ̀ wa tó ń tàn yòò

  Ń fògo f’Ọ́lọ́run.