Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

"Fi Ayọ̀ Kọrin" sí Jèhófà—Èyí tí Kò Lámì Orin

 ORIN 80

‘Tọ́ Ọ Wò, Kó O sì Rí I Pé Ẹni Rere Ni Jèhófà’

Yan Àtẹ́tísí
‘Tọ́ Ọ Wò, Kó O sì Rí I Pé Ẹni Rere Ni Jèhófà’
WÒÓ
Ọ̀rọ̀

(Sáàmù 34:8)

 1. 1. Ayọ̀ tá a ní kò láfiwé;

  A láǹfààní láti wàásù.

  Tọkàntọkàn ni ká fi ṣiṣẹ́ náà

  Ká lè ráwọn ẹni yíyẹ.

  (ÈGBÈ)

  Tọ́ ọ wò, kó o sì rí adùn rẹ̀ pé

  Jèhófà jẹ́ni rere.

  Bá a ṣe ń fọkàn sin Ọlọ́run wa,

  Ó ń bù kún ìsapá wa.

 2. 2. A mọyì àwọn ará wa

  Tó jẹ́ alákòókò kíkún.

  Ọ̀pọ̀ ìbùkún ń dúró de àwọn

  Tó fara síṣẹ́ Jèhófà.

  (ÈGBÈ)

  Tọ́ ọ wò, kó o sì rí adùn rẹ̀ pé

  Jèhófà jẹ́ni rere.

  Bá a ṣe ń fọkàn sin Ọlọ́run wa,

  Ó ń bù kún ìsapá wa.