Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

"Fi Ayọ̀ Kọrin" sí Jèhófà—Èyí tí Kò Lámì Orin

 ORIN 76

Báwo Ló Ṣe Máa Ń Rí Lára Rẹ?

Yan Àtẹ́tísí
Báwo Ló Ṣe Máa Ń Rí Lára Rẹ?

(Hébérù 13:15)

 1. 1. Báwo ló ṣe máa ń rí

  tó o bá ń ṣiṣẹ́ ìwàásù,

  tó ò ń gbìyànjú láti dé

  ọ̀dọ̀ àwọn èèyàn?

  Àwa gbẹ́kẹ̀ lé Jáà,

  yóò bù kún iṣẹ́ tá a ṣe,

  Torí Ó mọ àwọn tó

  jẹ́ ọlọ́kàn tútù.

  (ÈGBÈ)

  Inú wa dùn, ayọ̀ wa kún

  pé a ti ṣohun tá a lè ṣe.

  Kí Jèhófà tẹ́wọ́ gba ‘ṣẹ́

  tá à ń ṣe lójoojúmọ́.

 2. 2. Báwo ló ṣe máa ń rí

  tó o bá báwọn kan sọ̀rọ̀

  tí wọ́n tẹ́tí gbọ́rọ̀ rẹ,

  tó sì wọ̀ wọ́n lọ́kàn?

  Àwọn mí ì kọ̀ jálẹ̀,

  Wọn kò fẹ́ gbọ́ ọ̀rọ̀ wa.

  Síbẹ̀, à ń láyọ̀ pé à ń

  wàásù orúkọ Jáà.

  (ÈGBÈ)

  Inú wa dùn, ayọ̀ wa kún

  pé a ti ṣohun tá a lè ṣe.

  Kí Jèhófà tẹ́wọ́ gba ‘ṣẹ́

  tá à ń ṣe lójoojúmọ́.

 3.  3. Báwo ló ṣe máa ń rí

  tó o bá ń ṣiṣẹ́ Jèhófà,

  tó fi sí ìkáwọ́ wa,

  tó sì ń tì wá lẹ́yìn?

  À ń wá àwọn èèyàn

  tí wọ́n nífẹ̀ẹ́ òtítọ́.

  À ń sọ̀rọ̀ tútù lẹ́nu

  bá a ṣe ń wàásù fún wọn.

  (ÈGBÈ)

  Inú wa dùn, ayọ̀ wa kún

  pé a ti ṣohun tá a lè ṣe.

  Kí Jèhófà tẹ́wọ́ gba ‘ṣẹ́

  tá à ń ṣe lójoojúmọ́.