Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

"Fi Ayọ̀ Kọrin" sí Jèhófà—Èyí tí Kò Lámì Orin

 ORIN 56

Sọ Òtítọ́ Di Tìrẹ

Yan Àtẹ́tísí
Sọ Òtítọ́ Di Tìrẹ

(Òwe 3:1, 2)

 1. 1. Ọ̀nà òtítọ́ ló dára jù láti rìn,

  Àmọ́ ìwọ lo máa ṣèpinnu.

  Torí náà, ó sàn kó o gbàmọ̀ràn Jèhófà.

  Gbà pé òótọ́ ló ń sọ fún ọ.

  (ÈGBÈ)

  S’òótọ́ di tìrẹ.

  Kó hàn nínú ayé rẹ.

  Jèhófà yóò jẹ́

  Kó o láyọ̀ tòótọ́,

  Tó o bá s’òótọ́ di tìrẹ.

 2. 2. Bó o ṣe ńgbìyànjú, tóò ńlo ọ̀pọ̀ àkókò

  Lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn Ọlọ́run,

  Yóò mérè ńlá wá àtìyè àìnípẹ̀kun

  Lábẹ́ Ìjọba Ọlọ́run.

  (ÈGBÈ)

  S’òótọ́ di tìrẹ.

  Kó hàn nínú ayé rẹ.

  Jèhófà yóò jẹ́

  Kó o láyọ̀ tòótọ́,

  Tó o bá s’òótọ́ di tìrẹ.

 3. 3. Lójú Ọlọ́run, ọmọ kékeré la jẹ́.

  Ó yẹ ká jẹ́ kó tọ́ wa sọ́nà.

  Ká b’Ọ́lọ́run rìn lójoojúmọ́ ayé wa;

  Yóò bù kún wa lọ́pọ̀lọpọ̀.

  (ÈGBÈ)

  S’òótọ́ di tìrẹ.

  Kó hàn nínú ayé rẹ.

  Jèhófà yóò jẹ́

  Kó o láyọ̀ tòótọ́,

  Tó o bá s’òótọ́ di tìrẹ.