Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

"Fi Ayọ̀ Kọrin" sí Jèhófà—Èyí tí Kò Lámì Orin

 ORIN 53

À Ń Múra Láti Lọ Wàásù

Yan Àtẹ́tísí
À Ń Múra Láti Lọ Wàásù
WÒÓ
Ọ̀rọ̀

(Jeremáyà 1:17)

 1. 1. Ilẹ̀ mọ́.

  A ti ń múra

  Láti jáde lọ wàásù.

  Àmọ́ òjò ṣú,

  Ó wá bẹ̀rẹ̀ sí í rọ̀.

  Ó lè dà bíi ká dúró sílé,

  ká máa sùn.

  (ÈGBÈ))

  Èrò tó dáa ló yẹ kí a ní,

  Ká sì múra sílẹ̀.

  Ká bẹ Jáà pé kó ràn wá lọ́wọ́;

  Yóò gbé wa ró.

  Àwọn áńgẹ́lì wà lẹ́yìn wa,

  Jésù ló ń darí wọn.

  Pẹ̀lú ọ̀rẹ́ tòótọ́ lẹ́gbẹ̀ẹ́ wa,

  A ó ṣe é yọrí.

 2.  2. A ó láyọ̀

  Tí a bá ń fi

  Ìmọ̀ràn wọ̀nyí sọ́kàn.

  Jèhófà sì ń rí

  Gbogbo bá a ṣe ńsapá.

  A mọ̀ pé kò ní gbàgbé ìfẹ́

  tá à ń fi hàn.

  (ÈGBÈ))

  Èrò tó dáa ló yẹ kí a ní,

  Ká sì múra sílẹ̀.

  Ká bẹ Jáà pé kó ràn wá lọ́wọ́;

  Yóò gbé wa ró.

  Àwọn áńgẹ́lì wà lẹ́yìn wa,

  Jésù ló ń darí wọn.

  Pẹ̀lú ọ̀rẹ́ tòótọ́ lẹ́gbẹ̀ẹ́ wa,

  A ó ṣe é yọrí.