Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

"Fi Ayọ̀ Kọrin" sí Jèhófà—Èyí tí Kò Lámì Orin

 ORIN 49

Bá A Ṣe Lè Mú Ọkàn Jèhófà Yọ̀

Yan Àtẹ́tísí
Bá A Ṣe Lè Mú Ọkàn Jèhófà Yọ̀
WÒÓ
Ọ̀rọ̀

(Òwe 27:11)

 1. 1. A jẹ́jẹ̀ẹ́ láti ṣèfẹ́ Jáà.

  Àwa yóò máa hùwà ọgbọ́n.

  Tá a bá ńṣe bẹ́ẹ̀, à ń fi hàn pé

  A fẹ́ máa mú inú rẹ̀ dùn.

 2. 2. Ẹrú olóòótọ́, olóye

  Ń kéde ògo rẹ fáráyé.

  Wọ́n ń bọ́ wa lásìkò tó yẹ,

  Kí a lè máa ṣe ìfẹ́ rẹ.

 3. 3. Fún wa ní ẹ̀mí mímọ́ rẹ

  Ká lè jẹ́ olóòótọ́ sí ọ.

  Ká ṣohun tó máa gbé ọ ga,

  Ká sì máa mú inú rẹ dùn.