Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

"Fi Ayọ̀ Kọrin" sí Jèhófà—Èyí tí Kò Lámì Orin

 ORIN 42

Àdúrà Ìránṣẹ́ Ọlọ́run

Yan Àtẹ́tísí
Àdúrà Ìránṣẹ́ Ọlọ́run

(Éfésù 6:18)

 1. 1. Alágbára, Jèhófà Bàbá wa,

  Kórúkọ ńlá rẹ di sísọ di mímọ́.

  Alèwílèṣe, jọ̀ọ́, à ń bẹ̀ ọ́.

  À ń gbàdúrà kí Ìjọba rẹ dé.

  Lákòókò tó o ti ṣètò,

  Ká lè rí ìbùkún gbà.

 2. 2. O ṣé tó ò ń bù kún wa lójoojúmọ́.

  Àwọn ẹ̀bùn rere tó ò ńfún wa pọ̀ gan-an.

  Ò ń fún wa níyè àt’ìmọ́lẹ̀.

  Ò ń fún wa lọ́gbọ́n, ìmọ̀ àtòye.

  A ó máa dúpẹ́, a ó yìn ọ́

  Lójoojúmọ́ ayé wa.

 3. 3. Ìpọ́njú pọ̀ gan-an nínú ayé yìí.

  À ń wojú rẹ, jọ̀wọ́ wá tù wá nínú.

  Gbogbo àníyàn wa là ń kó wá.

  Fún wa lókun, má ṣe jẹ́ ká bọ́hùn.

  Jọ̀ọ́, jẹ́ ká lè ṣèfẹ́ rẹ,

  Ká sì mú ẹ̀jẹ́ wa ṣẹ.