Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

"Fi Ayọ̀ Kọrin" sí Jèhófà—Èyí tí Kò Lámì Orin

 ORIN 41

Jọ̀ọ́, Gbọ́ Àdúrà Mi

Yan Àtẹ́tísí
Jọ̀ọ́, Gbọ́ Àdúrà Mi
WÒÓ
Ọ̀rọ̀

(Sáàmù 54)

 1. 1. Jọ̀ọ́, gbọ́ orin tí mò ń kọ, Bàbá.

  Ọlọ́run mi, ìwọ ni mò ń sìn.

  Orúkọ ńlá rẹ kò láfiwé.

  (ÈGBÈ)

  Jọ̀ọ́ Jèhófà, gbọ́ àdúrà mi.

 2. 2. O ṣé Bàbá, tó o jẹ́ n rí òní.

  Mo wà láàyè, ò ń tọ́ mi sọ́nà.

  Mo mọrírì bó o ṣe ń ṣìkẹ́ mi.

  (ÈGBÈ)

  Jọ̀ọ́ Jèhófà, gbọ́ àdúrà mi.

 3. 3. Ohun tó tọ́ ni mo fẹ́ máa ṣe.

  Jẹ́ kí n lè máa rìn nínú ‘mọ́lẹ̀.

  Jọ̀ọ́, jẹ́ kí n lè ní ìfaradà.

  (ÈGBÈ)

  Jọ̀ọ́ Jèhófà, gbọ́ àdúrà mi.