Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

"Fi Ayọ̀ Kọrin" sí Jèhófà—Èyí tí Kò Lámì Orin

 ORIN 26

Ẹ Ti Ṣe É fún Mi

Yan Àtẹ́tísí
Ẹ Ti Ṣe É fún Mi
WÒÓ
Ọ̀rọ̀

(Mátíù 25:34-40)

 1. 1. Àwọn arákùnrin Kristi tó wà láyé

  ni àwọn àgùntàn mìíràn ńbá ṣiṣẹ́.

  Gbogbo ìsapá wọn

  láti ràn wọ́n lọ́wọ́

  Ni Jésù sọ pé wọ́n máa gba èrè rẹ̀.

  (ÈGBÈ)

  “Tẹ́ ẹ bá tù wọ́n nínú, ẹ tù mí nínú.

  Ohun tẹ́ ẹ ṣe fún wọn, èmi lẹ ṣe é fún.

  Iṣẹ́ tẹ́ ẹ ṣe fún wọn, èmi lẹ ṣe é fún.

  Bẹ́ ẹ ṣe ṣe é fún wọn, èmi lẹ ṣe é fún.

  Tẹ́ ẹ bá ti ṣe é fún wọn, ẹ ti ṣe é fún mi.”

 2. 2. “Nígbà tébi ń pa mí, tí òùngbẹ sì ń gbẹ mí,

  gbogbo ohun tí mo nílò lẹ pèsè.”

  Wọ́n béèrè pé: “Ìgbà wo

  la ṣe nǹkan wọ̀nyí?”

  Ọba náà máa dá wọn lóhùn, yóò sọ pé:

  (ÈGBÈ)

  “Tẹ́ ẹ bá tù wọ́n nínú, ẹ tù mí nínú.

  Ohun tẹ́ ẹ ṣe fún wọn, èmi lẹ ṣe é fún.

  Iṣẹ́ tẹ́ ẹ ṣe fún wọn, èmi lẹ ṣe é fún.

  Bẹ́ ẹ ṣe ṣe é fún wọn, èmi lẹ ṣe é fún.

  Tẹ́ ẹ bá ti ṣe é fún wọn, ẹ ti ṣe é fún mi.”

 3. 3. “Ẹ ti dúró tì mí, iṣẹ́ rere lẹ̀ ń ṣe.

  Ẹ̀ ń wàásù pẹ̀l’áwọn arákùnrin mi.”

  Ọba máa sọ fáwọn

  tó wà lọ́tùn-ún rẹ̀ pé:

  “Ẹ di pípé, kí ẹ sì jogún ayé.”

  (ÈGBÈ)

  “Tẹ́ ẹ bá tù wọ́n nínú, ẹ tù mí nínú.

  Ohun tẹ́ ẹ ṣe fún wọn, èmi lẹ ṣe é fún.

  Iṣẹ́ tẹ́ ẹ ṣe fún wọn, èmi lẹ ṣe é fún.

  Bẹ́ ẹ ṣe ṣe é fún wọn, èmi lẹ ṣe é fún.

  Tẹ́ ẹ bá ti ṣe é fún wọn, ẹ ti ṣe é fún mi.”