Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

"Fi Ayọ̀ Kọrin" sí Jèhófà—Èyí tí Kò Lámì Orin

 ORIN 22

Ìjọba Ọlọ́run Ti Ń Ṣàkóso​—⁠Jẹ́ Kó Dé!

Yan Àtẹ́tísí
Ìjọba Ọlọ́run Ti Ń Ṣàkóso​—⁠Jẹ́ Kó Dé!
WÒÓ
Ọ̀rọ̀

(Ìṣípayá 11:15; 12:10)

 1. 1. Jèhófà, o ti wà tipẹ́,

  Ìwọ yóò wà láéláé.

  O ti fàṣẹ yan Ọmọ rẹ;

  O gbé e gorí ìtẹ́.

  Ìjọba náà ti wà lọ́run;

  Yóò ṣàkóso ayé láìpẹ́.

  (ÈGBÈ)

  Ìgbàlà wa ti dé!

  Ìjọba Ọlọ́run bẹ̀rẹ̀.

  Jèhófà, a bẹ̀ ọ́,

  “Jọ̀wọ́, jẹ́ kó dé, jẹ́ kó dé!”

 2. 2. Àwọn áńgẹ́lì ńyọ̀ lọ́run,

  Wọ́n bú sórin ayọ̀.

  Torí a ti l’Éṣù jáde

  Kúrò ní àárín wọn.

  Ìjọba náà ti wà lọ́run;

  Yóò ṣàkóso ayé láìpẹ́.

  (ÈGBÈ)

  Ìgbàlà wa ti dé!

  Ìjọba Ọlọ́run bẹ̀rẹ̀.

  Jèhófà, a bẹ̀ ọ́,

  “Jọ̀wọ́, jẹ́ kó dé, jẹ́ kó dé!”

 3.  3. Sátánì yóò pa run láìpẹ́;

  Ìdáǹdè wa dé tán.

  À ń róhun tí ayé kò rí,

  Bí ìpọ́njú tiẹ̀ pọ̀.

  Ìjọba náà ti wà lọ́run;

  Yóò ṣàkóso ayé láìpẹ́.

  (ÈGBÈ)

  Ìgbàlà wa ti dé!

  Ìjọba Ọlọ́run bẹ̀rẹ̀.

  Jèhófà, a bẹ̀ ọ́,

  “Jọ̀wọ́, jẹ́ kó dé, jẹ́ kó dé!”