Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

"Fi Ayọ̀ Kọrin" sí Jèhófà—Èyí tí Kò Lámì Orin

 ORIN 19

Oúnjẹ Alẹ́ Olúwa

Yan Àtẹ́tísí
Oúnjẹ Alẹ́ Olúwa
WÒÓ
Ọ̀rọ̀

(Mátíù 26:26-30)

 1. 1. Jèhófà, Bàbá wa ní ọ̀run,

  Alẹ́ mímọ́ jù lọ nìyí,

  Tó o pinnu láti fagbára àtìfẹ́ hàn

  Pẹ̀lú ìdájọ́ òdodo.

  Ẹ̀jẹ̀ àgùntàn Ìrékọjá

  Lo fi gbàwọn èèyàn rẹ là.

  Alẹ́ yìí kan náà ni Kristi kú torí wa

  Kó lè mú àsọtẹ́lẹ̀ náà ṣẹ.

 2. 2. Búrẹ́dì tó wà níwájú wa

  Àti wáìnì ń rán wa létí

  Pé Jésù jólóòótọ́

  títí dójú ikú;

  Ohun ńlá lo san, Jèhófà.

  A ó máa ṣèrántí ikú Jésù.

  Alẹ́ yìí ń rán wa létí pé

  Ikú Ọmọ rẹ yìí

  lo fi rà wá pa dà.

  A moore ńlá tó o ṣe fún wa yìí.

 3.  3. O pè wá, a sì dá ọ lóhùn.

  A pé jọ ká lè jọ́sìn rẹ.

  O fìfẹ́ yọ̀ǹda Kristi

  Láti kú fún wa;

  A yìn ọ́, a yin Ọmọ rẹ.

  Ìrántí tá à ńṣe ńfògo fún ọ,

  Ó ń fún àwa náà nígbàgbọ́.

  A ó máa tẹ̀ lápẹẹrẹ tí Jésù fi lélẹ̀

  Ká lè rí ìyè àìnípẹ̀kun.