Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

"Fi Ayọ̀ Kọrin" sí Jèhófà—Èyí tí Kò Lámì Orin

 ORIN 126

Wà Lójúfò, Dúró Gbọn-in, Jẹ́ Alágbára

Yan Àtẹ́tísí
Wà Lójúfò, Dúró Gbọn-in, Jẹ́ Alágbára
WÒÓ
Ọ̀rọ̀

(1 Kọ́ríńtì 16:13)

 1. 1. Wà lójúfò, kó o dúró gbọn-in,

  Kó o sì jẹ́ alágbára.

  Ó dájú pé a óò ṣẹ́gun,

  Lábẹ́ ìdarí Jésù.

  A ṣe tán láti pàṣẹ rẹ̀ mọ́

  Bá a ti ń bá a lọ láti jagun náà.

  (ÈGBÈ)

  Dúró gbọn-in, má ṣe yẹsẹ̀ láéláé!

  Fara dà á títí dópin!

 2. 2. Wà lójúfò, kó o máa ṣọ́ra;

  Múra láti ṣègbọràn.

  Ẹrú olóòótọ́, olóye,

  Àwọn alàgbà ìjọ;

  Wọ́n ti ṣe tán láti bójú tó

  Àwọn àìní wa nípa tẹ̀mí.

  (ÈGBÈ)

  Dúró gbọn-in, má ṣe yẹsẹ̀ láéláé!

  Fara dà á títí dópin!

 3.  3. Ẹ wà lójúfò níṣọ̀kan;

  Máa fìgboyà wàásù lọ,

  Báwọn ọ̀tá tilẹ̀ ń gbógun,

  A ó wàásù títí dópin.

  Máa fayọ̀ sọ ìhìn rere náà,

  Ọjọ́ Jèhófà ti fẹ́rẹ̀ẹ́ dé!

  (ÈGBÈ)

  Dúró gbọn-in, má ṣe yẹsẹ̀ láéláé!

  Fara dà á títí dópin!