Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Àwa Kristẹni—Ìwé Ìpàdé  |  September 2017

 ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN | ÌSÍKÍẸ́LÌ 42-45

Ìjọsìn Mímọ́ Pa Dà Bọ̀ Sípò!

Ìjọsìn Mímọ́ Pa Dà Bọ̀ Sípò!

Jèhófà fi ìran tẹ́ńpìlì han Ìsíkíẹ́lì, kó bàa lè mú kí àwọn Júù tó wà nígbèkùn ronú pìwà dà, kó sì fi wọ́n lọ́kàn balẹ̀ pé ìjọsìn mímọ́ máa pa dà bọ̀ sípò. Bákan náà, ó tún ń rán wọn létí pé àwọn ìlànà Jèhófà fún ìjọsìn mímọ́ ga gan-an.

• Àwọn àlùfáà máa kọ́ àwọn èèyàn náà ní àwọn ìlànà Jèhófà

44:23

Sọ díẹ̀ lára àwọn ọ̀nà tí ẹrú olóòótọ́ àti olóye gbà kọ́ wa ní ìyàtọ̀ láàárín ohun tí kò mọ́ àti ohun tí ó mọ́. (kr 110-117)

• Àwọn èèyàn náà máa fọwọ́ sowọ́ pọ̀ pẹ̀lú àwọn tó ń mú ipò iwájú

45:16

Kí ni díẹ̀ lára àwọn ọ̀nà tá a lè gbà fi hàn pé à ń fọwọ́ sowọ́ pọ̀ pẹ̀lú àwọn alàgbà?