Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Àwa Kristẹni—Ìwé Ìpàdé  |  September 2017

 MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI

Kọ́ Wọn Láti Máa Sin Jèhófà Láìyẹsẹ̀

Kọ́ Wọn Láti Máa Sin Jèhófà Láìyẹsẹ̀

Àwọn ohun tá à ń rí fi hàn pé tí àwọn akéde bá tètè bẹ̀rẹ̀ sí í gba ìdálẹ́kọ̀ọ́ láti máa fi ìtara ṣe iṣẹ́ ìwàásù déédéé, irú wọn ló máa ń di akéde ògbóṣáṣá. (Owe 22:6; Flp 3:16) Àwọn àbá díẹ̀ rèé nípa bá a ṣe lè ran àwọn tá à ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lọ́wọ́ kí wọ́n lè ní ìpìlẹ̀ tó dára lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù:

  • Gbàrà tí ẹni tó ò ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì bá ti di akéde ni kó o ti bẹ̀rẹ̀ sí í dá a lẹ́kọ̀ọ́. (km 8/15 1) Jẹ́ kó mọ bó ti ṣe pàtàkì tó pé kó máa jáde òde ẹ̀rí lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀. (Flp 1:10) Máa sọ ohun tó dára gan-an nípa ìpínlẹ̀ ìwàásù yín. (Flp 4:8) Gbà á níyànjú pé kó bá alábòójútó àwùjọ àtàwọn míì ṣiṣẹ́ lóde ẹ̀rí kó bàa lè kẹ́kọ̀ọ́ láti inú ìrírí wọn.​—Owe 1:5; km 10/12 6 ¶3

  • Lẹ́yìn tí ẹni tó ò ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì bá ti ṣèrìbọmi, máa fún un níṣìírí nìṣó, kó o sì máa dá a lẹ́kọ̀ọ́ lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù, ní pàtàkì tí kò bá tíì ka ìwé Ẹ Dúró Nínú Ìfẹ́ Ọlọ́run tán.​—km 12/13 7

  • Ọ̀nà ìgbọ́rọ̀kalẹ̀ tó rọrùn ni kó o máa lò nígbà tó o bá ń ṣiṣẹ́ lóde ẹ̀rí pẹ̀lú ẹnì kan tó ṣẹ̀ṣẹ̀ di akéde. Tí akéde náà bá ti lo ọ̀nà ìgbọ́rọ̀kalẹ̀ kan, gbóríyìn fún un dáadáa. Kó o sì fún un ní àwọn àbá tó lè mú kó túbọ̀ tẹ̀ síwájú.​—km 5/10 7