Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Àwa Kristẹni—Ìwé Ìpàdé  |  September 2017

 ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN | ÌSÍKÍẸ́LÌ 46-48

Ohun Tí Àwọn Ọmọ Ísírẹ́lì Máa Gbádùn Tí Wọ́n Bá Kúrò Nígbèkùn

Ohun Tí Àwọn Ọmọ Ísírẹ́lì Máa Gbádùn Tí Wọ́n Bá Kúrò Nígbèkùn

Ìran tẹ́ńpìlì tí Ìsíkíẹ́lì rí fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì tó wà nígbèkùn ní ìṣírí, ó sì tún fi dá wọn lójú pé wọ́n ṣì máa kúrò nígbèkùn gẹ́gẹ́ bí àsọtẹ́lẹ̀ ṣe sọ. Ìjọsìn mímọ́ ni gbogbo àwọn tí Jèhófà ti bù kún á máa ṣe.

Ìran yẹn fi hàn pé nǹkan máa wà létòlétò, àwọn èèyàn á fọwọ́ sowọ́ pọ̀, Jèhófà sì máa dáàbò bò wọ́n

47:7-14

  • Ilẹ̀ ọlọ́ràá tó ń mú èso jáde

  • Ìdílé kọ̀ọ̀kan ló máa gba ogún

Kí wọ́n tó bẹ̀rẹ̀ sí í pín ilẹ̀ fún àwọn èèyàn, wọ́n á kọ́kọ́ ya apá ibi tó dára gan-an sọ́tọ̀ gẹ́gẹ́ bí “ọrẹ” fún Jèhófà

48:9, 10

Báwo ni mo ṣe lè fi hàn pé ìjọsìn Jèhófà ni mo kà sí pàtàkì jù nígbèésí ayé mi? (w06 4/15 27-28 ¶13-14)