Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Àwa Kristẹni—Ìwé Ìpàdé  |  September 2017

Àwọn Ọ̀nà Ìgbọ́rọ̀kalẹ̀ Tá A Lè Lò

Àwọn Ọ̀nà Ìgbọ́rọ̀kalẹ̀ Tá A Lè Lò

ILÉ ÌṢỌ́

Béèrè ìbéèrè: Ṣé àwọn áńgẹ́lì wà lóòótọ́?

Ka Bíbélì: Sm 103:20

Fi ìwé lọni: Ìwé ìròyìn Ilé Ìṣọ́ yìí ṣàlàyé ohun tí Bíbélì sọ nípa àwọn áńgẹ́lì àti ohun tí wọ́n ń ṣe fún wa báyìí.

MÁA FI ÒTÍTỌ́ KỌ́NI

Béèrè ìbéèrè: Ǹjẹ́ o rò pé ìmọ̀ sáyẹ́ǹsì ta ko Bíbélì?

Ka Bíbélì: Ais 40:22

Òtítọ́: Gbogbo ohun tí Bíbélì sọ nípa ìmọ̀ sáyẹ́ǹsì pátá ló péye.

ÌWÉ ÌKÉSÍNI SÍ ÀWỌN ÌPÀDÉ ÌJỌ (inv)

Fi ìwé lọni: Mo fẹ́ pè yín láti wá gbọ́ àsọyé kan tó dá lórí Bíbélì, ọ̀fẹ́ ni o. Ilé ìpàdé àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wà ládùúgbò yín la ti máa ṣe é. [Fún un ní ìwé ìkésíni, sọ àkókò àti àdírẹ́sì ibi tẹ́ ẹ ti máa ń ṣe ìpàdé ní òpin ọ̀sẹ̀, kó o sì sọ àkòrí àsọyé tẹ́ ẹ máa gbọ́ lọ́sẹ̀ yẹn.]

Béèrè ìbéèrè: Ṣé ẹ ti lọ sí ilé ìpàdé àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà rí? [Tó bá ṣeé ṣe, fi fídíò náà Kí Ló Máa Ń Ṣẹlẹ̀ Nínú Gbọ̀ngàn Ìjọba? hàn án.]

KỌ Ọ̀NÀ ÌGBỌ́RỌ̀KALẸ̀ RẸ

Wo àwọn ọ̀nà ìgbọ́rọ̀kalẹ̀ tá a fi ṣe àpẹẹrẹ yìí, kó o sì kọ ọ̀nà ìgbọ́rọ̀kalẹ̀ tìrẹ.