Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yan èdè Yorùbá

Àwọn akéde kan ń pe àwọn èèyàn wá sí ìpàdé ní Cook Islands

ÌWÉ ÌPÀDÉ ÌGBÉSÍ AYÉ ÀTI IṢẸ́ ÒJÍṢẸ́ ÀWA KRISTẸNI September 2017

Àwọn Ọ̀nà Ìgbọ́rọ̀kalẹ̀ Tá A Lè Lò

Àwọn ọ̀nà ìgbọ́rọ̀kalẹ̀ tá a lè lò láti fi ìwé ìròyìn Ilé Ìṣọ́ lọni àti láti kọ́ni pé gbogbo ohun tí Bíbélì sọ nípa ìmọ̀ sáyẹ́ńsì pátá ló péye. Lo àbá yìí láti fi kọ ìgbọ́rọ̀kalẹ̀ rẹ.

ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN

Ìjọsìn Mímọ́ Pa Dà Bọ̀ Sípò!

Jèhófà fi ìran tẹ́ńpìlì han Ìsíkíẹ́lì, kó bàa lè mú kí àwọn Júù tó wà nígbèkùn ronú pìwà dà, kó sì fi wọ́n lọ́kàn balẹ̀ pé ìjọsìn mímọ́ máa pa dà bọ̀ sípò.

MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI

Kí Nìdí Tó O Fi Mọyì Ìjọsìn Mímọ́?

Ìjọsìn mímọ́ ti fìdí múlẹ̀ gbọn-in gbọn-in. Ǹjẹ́ o máa ń ronú nígbà gbogbo nípa àǹfààní tó o ní láti mọ Jèhófà, tó o sì ń sìn ín?

ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN

Ohun Tí Àwọn Ọmọ Ísírẹ́lì Máa Gbádùn Tí Wọ́n Bá Kúrò Nígbèkùn

Ìran tí Ìsíkíẹ́lì rí fi hàn pé nǹkan máa wà létòlétò, àwọn èèyàn á fọwọ́ sowọ́ pọ̀, Jèhófà sì máa dáàbò bò wọ́n.

ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN

Jèhófà Máa San Wá Lẹ́san Tá A Bá Jẹ́ Adúróṣinṣin sí I

Ìtàn àwọn Hébérù mẹ́ta yẹn ń fún wa níṣìírí láti jẹ́ adúróṣinṣin sí Jèhófà Ọlọ́run.

MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI

Jẹ́ Adúróṣinṣin Nígbà Ìdẹwò

Jésù Kristi jẹ́ adúróṣinṣin sí Jèhófà nígbà ìdẹwò. Ṣé àwa èèyàn aláìpé lè jẹ́ adúróṣinṣin nígbà táwọn èèyàn bá ń fẹ́ ká ṣe ohun tó máa sọ wá di aláìdúróṣinṣin sí Ọlọ́run?

MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI

Jẹ́ Adúróṣinṣin Nígbà Tí Wọ́n Bá Yọ Mọ̀lẹ́bí Rẹ Kan Lẹ́gbẹ́

Ohun tá a bá ṣe nígbà tí wọ́n bá yọ mọ̀lẹ́bí wa kan lẹ́gbẹ́ máa fi hàn bóyá adúróṣinṣin ni wá tàbí a kì í ṣe adúróṣinṣin. Kí ló lè ràn wá lọ́wọ́ ká lè jẹ́ adúróṣinṣin?

ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN

Ṣé Ò Ń Sin Jèhófà Láìyẹsẹ̀?

Dáníẹ́lì sin Ọlọ́run láìyẹsẹ̀. Kò gbà kí ohunkóhun dí òun lọ́wọ́ láti máa sin Ọlọ́run nìṣó.

MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI

Kọ́ Wọn Láti Máa Sin Jèhófà Láìyẹsẹ̀

Tètè bẹ̀rẹ̀ sí í kọ́ àwọn tó ṣẹ̀ṣẹ̀ di akéde láti máa fi ìtara ṣe iṣẹ́ ìwàásù déédéé. Ran àwọn tó ò ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lọ́wọ́ kí wọ́n lè di akéde ògbóṣáṣá.