Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Àwa Kristẹni—Ìwé Ìpàdé  |  September 2016

 ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN | SÁÀMÙ 119

“Máa Rìn Nínú Òfin Jèhófà”

“Máa Rìn Nínú Òfin Jèhófà”

Ohun tó túmọ̀ sí láti máa rìn nínú òfin Jèhófà ni pé, ká máa fi tinútinú tẹ̀ lé àwọn ìtọ́sọ́nà Ọlọ́run. Bíi ti onísáàmù náà, Bíbélì sọ̀rọ̀ nípa ọ̀pọ̀ àwọn míì tó ṣègbọràn sí òfin Jèhófà, tí wọ́n sì gbára lé e.

Tá a bá fẹ́ ní ojúlówó ayọ̀, a gbọ́dọ̀ máa rìn nínú òfin Ọlọ́run

119:1-8

Jóṣúà fi hàn pé òun gbára lé ìtọ́ni Jèhófà pátápátá. Ó mọ̀ pé tí òun bá fẹ́ ṣàṣeyọrí kí òun sì tún láyọ̀, òun gbọ́dọ̀ gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà pẹ̀lú gbogbo ọkàn òun

Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run máa ń fún wa ní ìgboyà láti fara da àwọn ìṣòro

119:33-40

Jeremáyà ní ìgboyà, ó sì gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà nígbà ìṣòro. Kò kó àwọn nǹkan tara jọ, ó sì lo ìfaradà lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn rẹ̀

Tá a bá ní ìmọ̀ tó péye nípa Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, èyí á jẹ́ ká máa fi ìgboyà wàásù

119:41-48

Pọ́ọ̀lù kì í bẹ̀rù láti wàásù ọ̀rọ̀ Ọlọ́run fún ẹnikẹ́ni. Ó dá a lójú pé Jèhófà máa ran òun lọ́wọ́ nígbà tó fìgboyà wàásù fún Gómìnà Fẹ́líìsì

Àwọn ibo ni mo ti lè fìgboyà wàásù fún àwọn ẹlòmíì?

  • Nílé ìwé

  • Níbi iṣẹ́

  • Nínú ìdílé

  • Níbòmíì