Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Àwa Kristẹni—Ìwé Ìpàdé  |  September 2016

 ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN | SÁÀMÙ 142-150

“Jèhófà Tóbi, Ó sì Yẹ fún Ìyìn Gidigidi”

“Jèhófà Tóbi, Ó sì Yẹ fún Ìyìn Gidigidi”

145:1-5

Dáfídì rí i pé títóbi Jèhófà kò ní ààlà, ìyẹn sì mú kó sọ pé òun á máa yin Jèhófà títí ayé

145:10-12

Bíi ti Dáfídì, gbogbo ìgbà làwọn olóòótọ́ ìránṣẹ́ Jèhófà máa ń sọ̀rọ̀ nípa agbára ńlá rẹ̀

145:14

Ó dá Dáfídì lójú pé ó máa ń wu Jèhófà láti ṣìkẹ́ àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ àti pé ó lágbára láti ṣe bẹ́ẹ̀