Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Àwa Kristẹni—Ìwé Ìpàdé  |  September 2016

 MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI

Mú Kí Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Rẹ Sunwọ̀n Sí I—Máa Fún Àwọn Tó Bá Nífẹ̀ẹ́ sí Ọ̀rọ̀ Wa Níṣìírí Láti Wá sí Ìpàdé

Mú Kí Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Rẹ Sunwọ̀n Sí I—Máa Fún Àwọn Tó Bá Nífẹ̀ẹ́ sí Ọ̀rọ̀ Wa Níṣìírí Láti Wá sí Ìpàdé

ÌDÍ TÓ FI ṢE PÀTÀKÌ: Láwọn ìpàdé wa, a máa ń ‘kọ orin sí Jèhófà’ a sì tún máa ń ‘fi ìyìn fún un.’ (Sm 149:1) A máa ń kọ́ bá a ṣe lè ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run láwọn ìpàdé wa. (Sm 143:10) Àwọn tó bá fìfẹ́ hàn àti àwọn akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì sábà máa ń tẹ̀ síwájú gan-an tí wọ́n bá ti bẹ̀rẹ̀ sí í wá sáwọn ìpàdé wa.

BÓ O ṢE LÈ ṢE É:

  • Má ṣe jẹ́ kó pẹ́ kó o tó pè wọ́n wá sí ìpàdé. Má ṣe dúró dìgbà tí ìkẹ́kọ̀ọ́ bá fẹsẹ̀ múlẹ̀.—Iṣi 22:17

  • Ṣàlàyé bá a ṣe máa ń ṣe ìpàdé fún ẹni tó fìfẹ́ hàn náà, kó o sì jẹ́ kó mọ ohun tá a máa gbádùn nípàdé tó ń bọ̀. Àwọn nǹkan tó o lè lò rèé: Ìwé ìkésíni sí àwọn ìpàdé ìjọ, fídíò náà Kí Ló Máa Ń Ṣẹlẹ̀ Nínú Gbọ̀ngàn Ìjọba?, àti ẹ̀kọ́ 5 àti 7 nínú ìwé Àwọn Wo Ló Ń Ṣe Ìfẹ́ Jèhófà Lóde Òní?

  • Ràn wọ́n lọ́wọ́. Ṣé ẹni náà fẹ́ kí ẹnì kan fi mọ́tò tàbí ohun ìrìnnà míì gbé òun lọ sí ìpàdé? Ṣé o lè bá a yan aṣọ tó bójú mu? Jókòó tì í ní ìpàdé, kẹ́ ẹ sì jọ máa lo àwọn ìtẹ̀jáde tá a bá ń lò. Fi ojú rẹ̀ mọ àwọn míì nínú ìjọ