Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Àwa Kristẹni—Ìwé Ìpàdé  |  September 2016

 ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN | SÁÀMÙ 135-141

Ọlọ́run Ṣẹ̀dá Wa Tìyanu-Tìyanu

Ọlọ́run Ṣẹ̀dá Wa Tìyanu-Tìyanu

Dáfídì ṣe àṣàrò lórí àwọn ànímọ́ rere tí Ọlọ́run ní, èyí tó hàn nínú ìṣẹ̀dá. Ọkàn rẹ̀ balẹ̀ bó ṣe ń fi ayé rẹ̀ sin Jèhófà.

Nígbà tí Dáfídì ronú jinlẹ̀ nípa ìṣẹ̀dá, èyí mú kó yin Jèhófà:

139:14

  • “Èmi yóò gbé ọ lárugẹ, nítorí pé lọ́nà amúnikún-fún-ẹ̀rù ni a ṣẹ̀dá mi tìyanu-tìyanu”

139:15

  • “Àwọn egungun mi kò pa mọ́ fún ọ, nígbà tí a ṣẹ̀dá mi ní ìkọ̀kọ̀, nígbà tí a hun mí ní àwọn apá ìsàlẹ̀ jù lọ ní ilẹ̀ ayé”

139:16

  • “Àní ojú rẹ rí ọlẹ̀ mi, inú ìwé rẹ sì ni gbogbo àwọn ẹ̀yà rẹ̀ wà ní àkọsílẹ̀”