ILÉ ÌṢỌ́

Béèrè ìbéèrè: Gbogbo wa la máa ń nílò ìtùnú lọ́pọ̀ ìgbà. Àmọ́, ibo la ti lè rí i?

Ka Bíbélì: 2Kọ 1:3, 4

Fi ìwé lọni: Ìwé ìròyìn Ilé Ìṣọ́ yìí ṣàlàyé bí Ọlọ́run ṣe máa ń tù wá nínú.

ILÉ ÌṢỌ́ (ẹ̀yìn ìwé)

Béèrè ìbéèrè: Ọ̀pọ̀ èèyàn rò pé ohun tí Ìjọba Ọlọ́run túmọ̀ sí ni pé kí Ọlọ́run máa jọba lọ́kàn èèyàn; àwọn míì sì rò pé ó jẹ́ ọ̀nà tí àwa èèyàn máa gbà mú àlàáfíà wá sáyé. Kí lèrò rẹ?

Ka Bíbélì: Da 2:44

Fi ìwé lọni: Ẹsẹ Bíbélì yìí jẹ́ ká mọ̀ pé ìjọba gidi kan ni Ìjọba Ọlọ́run. Àpilẹ̀kọ yìí sọ àwọn nǹkan míì tí Bíbélì sọ nípa Ìjọba Ọlọ́run.

MÁA FI ÒTÍTỌ́ KỌ́NI

Béèrè ìbéèrè: Báwo la ṣe lè mọ̀ bóyá Ọlọ́run bìkítà nípa wa?

Ka Bíbélì: 1Pe 5:7

Òtítọ́: Ọlọ́run ń fẹ́ ká máa gbàdúrà sí òun torí pé ó bìkítà nípa wa.

KỌ Ọ̀NÀ ÌGBỌ́RỌ̀KALẸ̀ RẸ

Wo àwọn ọ̀nà ìgbọ́rọ̀kalẹ̀ tá a fi ṣe àpẹẹrẹ yìí, kó o sì kọ ọ̀nà ìgbọ́rọ̀kalẹ̀ tìrẹ.