Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Àwa Kristẹni—Ìwé Ìpàdé  |  October 2017

 MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI

Fi Ayé Rẹ Yin Jèhófà!

Fi Ayé Rẹ Yin Jèhófà!

Ẹ̀mí ṣeyebíye gan-an. Àwọn ohun tá à ń ṣe lójoojúmọ́ máa ń fi hàn bóyá a mọyì ẹ̀mí wa tàbí a ò mọyì rẹ̀. Àwa èèyàn Jèhófà máa ń sapá láti rí i pé a lo àwọn ẹ̀bùn wa láti yin Jèhófà àti láti bọlá fún un, torí pé òun ni Orísun Ìyè. (Sm 36:9; Iṣi 4:11) Àmọ́ tá ò bá múra, nítorí kòókòó-jàn-án-jàn-án inú ayé burúkú yìí, a lè dẹni tí kò fọwọ́ pàtàkì mú àwọn nǹkan tẹ̀mí mọ́. (Mk 4:​18, 19) Ó wá yẹ kẹ́nì kọ̀ọ̀kan bi ara rẹ̀ pé: ‘Ṣé ohun tó dára jù lọ ni mò ń fún Jèhófà? (Ho 14:⁠2) Ṣé iṣẹ́ mi kò ti fẹ́ gba ìjọsìn Jèhófà mọ́ mi lọ́wọ́? Kí ni àwọn nǹkan tẹ̀mí tí mo pinnu láti ṣe? Báwo ni mo ṣe lè ṣe púpọ̀ sí i lẹ́nu iṣẹ́ òjísẹ́ mi?’ Tó o bá rí i pé o nílò àtúnṣe, bẹ Jèhófà pé kó ràn ẹ́ lọ́wọ́ kó o lè ṣe bẹ́ẹ̀. Ó dájú pé tá a bá ń fi ayé wa yin Jèhófà lójoojúmọ́, a máa láyọ̀, ìgbésí ayé wa á sì lóyin!​—Sm 61:8.

Ta ni ìwọ ń lo ẹ̀bùn rẹ fún?

WO FÍDÍÒ NÁÀ LO Ẹ̀BÙN Ẹ FÚN IṢẸ́ ÌSÌN JÈHÓFÀ, LẸ́YÌN NÁÀ DÁHÙN ÀWỌN ÌBÉÈRÈ YÌÍ:

  • Kí nìdí tí kò fi bọ́gbọ́n mu láti lo àwọn ẹ̀bùn wa fún ayé Sátánì? (1Jo 2:17)

  • Tá a bá fún Jèhófà ní ohun tó dára jù, àwọn ìbùkún wo la máa rí?

  • Àwọn ọ̀nà míì wo lo lè gbà lo ẹ̀bùn rẹ lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn mímọ́?