Ṣé ìwọ náà fẹ́ jẹ́ olóòótọ́ nígbà àdánwò bíi Dáníẹ́lì? Dáníẹ́lì kẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run jinlẹ̀, títí kan àwọn àsọtẹ́lẹ̀ tó ta kókó. (Da 9:⁠2) Tó o bá ń kẹ́kọ̀ọ́ jinlẹ̀ nínú Bíbélì, báwo nìyẹn ṣe lè mú kó o jẹ́ olóòótọ́? Ó lè jẹ́ kó túbọ̀ dá ẹ lójú pé àwọn ìlérí Jèhófà máa ṣẹ. (Joṣ 23:14) Ó tún lè jẹ́ kó o túbọ̀ nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run, èyí á sì jẹ́ kó máa wù ẹ́ láti ṣe ohun tó tọ́. (Sm 97:10) Àmọ́, ibo ló yẹ kó o ti bẹ̀rẹ̀? Wo àwọn àbá yìí.

  • Àwọn nǹkan wo ni mo lè kẹ́kọ̀ọ́? Ọ̀kan pàtàkì lára ọ̀nà tó o lè máa gbà kẹ́kọ̀ọ́ ni pé kó o máa múra ìpàdé sílẹ̀. Wàá túbọ̀ máa gbádùn Bíbélì kíkà ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀ tó o bá ń wá àyè láti ṣèwádìí nípa àwọn nǹkan tí kò bá yé ẹ. Bákan náà, àwọn kan tún máa ń kẹ́kọ̀ọ́ nípa àwọn àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì, oríṣiríṣi apá tí èso tẹ̀mí pín sí, àwọn ibi tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù rìrìn-àjò míṣọ́nnárì dé tàbí àwọn ìṣẹ̀dá Jèhófà. Tí ìbéèrè kan bá wá sí ẹ lọ́kàn tó o sì fẹ́ ṣèwádìí nínú Bíbélì, kọ ọ́ sílẹ̀ kó o sì fi kún ará ohun tó o máa kẹ́kọ̀ọ́.

  • Ibo ni mo ti lè rí ìsọfúnni? Kó o lè mọ ohun tí wàá ṣe, wo fídíò náà Àwọn Ohun Tá A Lè Fi Ṣèwádìí Láti Rí Ìṣúra Tẹ̀mí. Bí àpẹẹrẹ, o lè dán ara rẹ wò, kó o ṣèwádìí nípa àwọn agbára ayé tí ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn ẹranko tó wà nínú Dáníẹ́lì orí ìkeje ń ṣàpẹẹrẹ.

  • Báwo ló ṣe yẹ kí àkókò tí mo fi ń kẹ́kọ̀ọ́ gùn tó? Tó o bá ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì déédéé, àjọṣe rẹ pẹ̀lú Jèhófà á lágbára dáadáa. Tó o bá kọ́kọ́ bẹ̀rẹ̀, o lè máa lo àkókò díẹ̀, tó bá yá o lè máa fi kún àkókò tó o fi ń kẹ́kọ̀ọ́ díẹ̀díẹ̀. Ńṣe ni ìkẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run dà bí ìgbà tí èèyàn ń wá àwọn ohun iyebíye lábẹ́ ilẹ̀; bí àwọn ohun iyebíye tó ò ń rí bá ṣe ń pọ̀ sí i, bẹ́ẹ̀ ni á ṣe máa wù ẹ́ tó láti túbọ̀ walẹ̀ jìn! (Owe 2:​3-6) Wàá túbọ̀ máa nífẹ̀ẹ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì á sì di ohun tó o yàn láàyò.​—1Pe 2:2.

KÍ NI ÀWỌN ẸRANKO ẸHÀNNÀ INÚ DÁNÍẸ́LÌ ORÍ ÌKEJE DÚRÓ FÚN?

ÀFIKÚN ÌBÉÈRÈ:

Báwo ni àsọtẹ́lẹ̀ tó wà ní Dáníẹ́lì 7:8, 24 ṣe ṣẹ?

ÌKẸ́KỌ̀Ọ́ TÓ KÀN:

Kí ni àwọn ẹranko tó wà nínú Ìsípayá orí 13 ṣàpẹẹrẹ?