Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Àwa Kristẹni—Ìwé Ìpàdé  |  October 2016

 ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN | ÒWE 22-26

“Tọ́ Ọmọdékùnrin Ní Ọ̀nà Tí Yóò Tọ̀”

“Tọ́ Ọmọdékùnrin Ní Ọ̀nà Tí Yóò Tọ̀”

Ìwé Òwe ní ọ̀pọ̀ ìmọ̀ràn tó wúlò gan-an fún àwọn òbí. Bí àpẹẹrẹ, ibi tí wọ́n bá tẹ ẹ̀ka igi kan sì nígbà tó ṣẹ̀ṣẹ̀ ń hù ló máa pinnu bí igi náà ṣe máa rí tó bá dàgbà. Bákan náà ni àwọn ọmọ tí wọ́n tọ́ dáadáa ṣe sábà máa ń bá a lọ láti sin Jèhófà nígbà tí wọ́n bá dàgbà.

22:6

  • Ó máa ń gba ìsapá àti ọ̀pọ̀ àkókò kéèyàn tó lè tọ́ ọmọ kan dáadáa

  • Àwọn òbí gbọ́dọ̀ jẹ́ àpẹẹrẹ rere fún àwọn ọmọ wọn, kí wọ́n fara balẹ̀ kọ́ wọn, kí wọ́n gbà wọ́n níyànjú, kí wọ́n fún wọn níṣìírí, kí wọ́n sì máa bá wọn wí

22:15

  • Ìbáwí jẹ́ ìdálẹ́kọ̀ọ́ tó máa ń yí èrò àti ìṣe ẹni pa dà sí rere

  • Kì í ṣe irú ìbáwí kan náà ló máa ń wúlò fún gbogbo ọmọ