Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Àwa Kristẹni—Ìwé Ìpàdé  |  October 2016

 MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI

Ṣé O Máa Ń Lo Káàdì Ìkànnì JW.ORG?

Ṣé O Máa Ń Lo Káàdì Ìkànnì JW.ORG?

Iṣẹ́ ìwàásù ti wá di kánjúkánjú gan-an báyìí, torí pé ìpọ́njú ńlá ti sún mọ́lé. (Owe 24:11, 12, 20) Ká báa lè ran àwọn èèyàn lọ́wọ́, a lè lo káàdì ìkànnì JW.ORG láti darí wọn sínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run tàbí sí ìkànnì wa. Káàdì náà ní àmì ìlujá tó máa darí wọn sí fídíò kan tá a pe àkọlé rẹ̀ ní Kí Nìdí Tó Fi Yẹ Kó O Kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì? àti apá tó máa jẹ́ kí wọ́n lè béèrè ìsọfúnni púpọ̀ sí i tàbí ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lórí ìkànnì wa. Kì í yá àwọn kan lára láti gba àwọn ìwé wa, àmọ́ ó lè wù wọ́n láti lọ sí ìkànnì wa. O lè fún wọn ní káàdì náà. Àmọ́ ṣá o, má ṣe fi káàdì náà sílẹ̀ fún àwọn tí kò fẹ́ gbọ́ ọ̀rọ̀ wa.

Tó o bá fẹ́ bá ẹnì kan sọ̀rọ̀ nígbà tí o kò sí lóde ẹ̀rí, o lè sọ pé: “Mo ní ohun kan tí mo fẹ́ fún un yín. Káàdì yìí máa darí yín sí ìkànnì kan tó láwọn ìsọfúnni lóríṣiríṣi àtàwọn fídíò tó dá lórí onírúurú nǹkan.” (Jo 4:7) Pélébé la ṣe káàdì náà, èyí sì máa jẹ́ kó rọrùn fún ẹ láti mú mélòó kan dání nígbà tó o bá ń jáde, kó o lè lò ó nígbàkigbà tí àyè rẹ̀ bá yọ.